Sunday, July 12, 2009

NITORI OWO ORI, WON BE ORI OBA ALAYE

E yi ko jo ogun ogun abele ti o koja, kosi jo ija oselu Egbe Action, ko ni i se pelu ija ti o wa ye ni Ile Igbimo Asofin Iwo Oorun, bee ni ko tan mo ija 'Weti e' ti odun 1966, ti o je ki ologun gba ijoba.
Ija yii ti o wa ye ni odun 1969, je ti ija owo ori, ti o laami laaka ninu itan ifi ehonu han ni ile wa Naijiria.
Isele buburu ati iwa alailaanu omo eniyan yii je eyi ti o waye ni ilu Ogbomoso, ti awon emewa oba Olajide Olayode be ori re. Won ko da duro bee, won tu gbe ara ti o ku kaaakiri yi gbogbo ilu Ogbomoso ka.
Awon oloye paapa naa n fi ori oba han kaakiri igboro, titi, ti won fi gbe pamo ti won ko gbe jade mo.
Isele yii bere ni Akanran ni Agbegbe idagbasoke Ibadan East (Ibadan East District Council) ati Ogunmakin, Agbegbe idagbasoke Egba(Egba District Council), nigba ti awon ara agbegbe mejeeji yii tu jade lati fi ehonu won han si iru owo ori ti Ijoba Iwo oorun gbe jade.
Ijoba Iwo oorun nigba naa, labe idari Ogagun Adeyinka Adebayo ti gbero lati mulele mo awon ti ko ba san owo ori 1968/69 ki o to di ojo1, osu Agemo (osu keje), odun 1969.
Ni afikun, awon ara ilu kan ri owo ori naa pe "o ti poju". Ni awon opo aaye ni ilu naa gbogbo won n sare lo san owo ki ojo to pe, sugbon eyi ti awon ara Akanran ati Ogunmakin o ba fi lo san owo gege bi omo orileede rere, awon ara abule yi dena ati wole fun awon olowoori ati awon olopaa ni, koda ki won to wole wa se ise won ni won ti n de na.
Ko si ibikan kan kaakiri agbaye ti ti ara ilu ti n pase pe iye bayi ni awon yoo san ni owo ori, ijoba Iwo oorun ko ba ki ti oun je oloto.
Ija owo ori ti odun 1969, yen je atele ti odun 1968. Owo ori ti mekunnu n san je sile oyinbo 3.5, eyi ni awon ijoba ibile fi sile pe ki won ma san lati pese ohun amaye derun silu ni agbegbe won. Gbogbo owo ori ti ijoba apapo ngba lowo Ijoba Iwo oorun nigba naa je sile oyinbo milionu 2.3 ni odun je owo 'ti ko ga ni lara, pelu iye ti ijoba n na la ti pese nnkan meremere si ilu' bi Adebayo ti so.
Ni Akanran, awon ara abule go de awon olopaa ti o wa mu awon ti ko san owo ori pelu nnkan ija oloro, won pa olopaa meta, won si se opolopo lese. Won sa kuro ni ilu, won si n ri oku awon eeyan ti won fi ewe bo laaarin ona, o le ni 1000 awon ti o n fi ehonu han ti awon olopaa mu ni Ibadan ati agbegbe re.
Ija owo ori ti Ogbomoso lo da kolu kogba sile, nigba ti awon ti o n fi ehonu won han ko lu aafin Oba Olajide Olayode ti won si fi ada pa. Won wo Soun jade si oju popona, won pa, won be ori re ati ese re won wa n gbe kukute re kaakiri awon ti won o fe san owo ori, won n ko orin ogun.
Won tun pa awon elomiran pelu oloye Ogbomoso meta, iyen awon onija owo ori.
Awon ti o n ja naa yabo aafin Soun pelu awon ohun ija oloro, ni wahala ba be sile. Nigba ti oba ti ri awon elehonu naa ni o ti na papa bora gba ile okan ninu awon ijoye re lo, awon elehonu naa ba gbaya, o di ile oloye naa.
Won pase fun pe ki o mu oba jade ki o si sa asala fun emi re, oloye naa sa lo nigba ti awon elehonu naa wo oba sita si aarin oju ona ti won si pa. Won ba ero telifoonu je ko si ona fun eni keni lati pe jade tabi pe wole mo. Won tun di ona ti o wo Ogbomoso lati Ibadan ati Ilorin pa.
Opolopo awon eeyan sa asala fun emi won nigba ti won ni ki awon eso ologun lo se eto bi alaafia yoo se joba nibe. Won ni won mu opolopo awon elehonu ti won ko so iye won.
Won bi Oba Olayode ni Ogbomoso ni odun 1921, won si fi joye Soun ti Gomina akoko funIpinle Iwo Oorun Ogagun Adekunle Fajuyi gbe opa ase le lowo ninu osu keje ojo 22 odun 1966. O gbade lowo oloogbe Oba Elepo 11, olori mewa ati omomejila ni o gbeyin re.
Nigba ti won fe sin Oba Olayode, won ko ri ori ati ese re, won sin oba naa leyin etutu oba ni ojo keji ti o ku, la i lori.
Leyin ti won ti ni ki awon ologun lo petu si agbegbe naa, ogagun fun agbegbe naa ni Ibadan, Ogagun Oluwole Rotimi pe awon eeyan Iwo oorun pe ki won lo ti owo omo won bo aso ki won ye ja ni gbogbo igba lati le je ki ijoba raye doju ko ogun Ojukwu ti o n lo lowo.
Ni odun 1966, Ogagun Adeyinka Adebayo teti beleje si ero awon eeyan lori oro owo ori, o yan ajo kan ti o pe ni Ajo Ayoola(Ayoola commission), ajo yii gbo gbogbo isoro awon eeyan o si se bi o ti to, o si jabo fun ijoba. Ijoba si gba lati tele ilana ajo naa, paapaa eyi ti o ni se pelu awon agbe.
O so fi ehonu re ran lori isele naa pe ki i se awon ologun tabi awon olpaa ni o fa isele naa, paapaa pipa oba, o ni awon alagbara kan ni o wa leyin isele naa, o ni ijoba ti fi iya je awon ti o po lori isele naa, bakan naa ni won si n sise lo lati mu awon ti o ku. Ko si eni ti o ma bo lowo ofin ninu gbogbo won. Awon ti won ba je bi won o ko won si atimole fun iye odun ti o ba ye won labe ofin.

Sunday, June 28, 2009

ABAMI OLOGBO DUDU N BA GOMINA JA LORU

Gomina oloselu ana kan ni a gbo pe abami ologbo dudu kan n ke kiri laaarin ile re ni aipe yii, nigba ti kuru kere ayeye odun kan ibo June 12 n jo lowo.
Gomina pupa naa ti ede ilu oke dun mo lenu ju ede miran lo salaye pe "titi ti o fi sele si emi naa, mo ti ma n ro pe aroso lasan ni emi esu ti awon eeyan ma n pa ri wo.
Ni tooto, mo ti gbo, mo si ti ri orisirisi iriri ti o je ti aje ati oso, sugbon mi o ti ri di otito titi di asiko ti mo ri iriri aye bee fun ra ra mi.
Orisirisi ni a ti gbo nipa awon omo ikoko ti won bi pelu ami orisirisi ni ara, eyi ni ami pe won ti bi won leekan tabi ju be e lo ri ni abiku, tabi ki a so pe emere tabi elemere omo ni won.
Ni afikun, mo ti ri awon aje ti o ka ni ita gbangba laaarin ilu ri, ti awon eeyan ti inu m bi si ju won lokoo pa. Awon kan ti so nipa awon oogun ti won so sinu soobu itaja won, ti won so mo oke tabi sinu ikoko ti won so sinu ofiisi won, gege bi ise awon eni ibi.
Awon miran tile tun ti so nipa awon ise ibi miran ti o ma n sele ni asale lati oju iran tabi nipa ala lila. Awon miran tile ma n so pe awon ma ri ni oju koroju iru awon eranko ti ko dara miran ni inu yara won. Awon eranko bi ologbo, ati orisirisi eye bi owiwi ati adan.
Ojo keji osu yii ni nkan bii aago kan oru, ni mo gbo ti nnkan kan jabo lati ori orule bii irin ti o dun nile, eyi jimi loju oorun.
Bi mo se ji, mo ayika yara mi, ko si enikan kan ti o n rin, nigba ti mo wo aago, aago kan ni o lu. Mi o riran daradara nitori ina ti o wa kere bi omo ina igun, to ri ina mona mona ko riran daradara. Atupa gan an ti mo tan, mo ti yi lo sile kin to sun, sugbon ju gbogbo re lo, eeyan le ri nnkan die die.
Eru wa m ba mi pe abi awon ota June 12, ti de pelu ise won ni, bo ya won tun ti ran awon onise ibi wa gege bi ise awon oloselu buruku.
Orisirisi ero ni o n wa simi lokan, nigba ti kini naa ti dun, mo wa ni ki n gba adura die, nitori abajade esi ipade kan ti a se ni ano ti o je pe emi gan an ni mo yari ju nibe pe a o ni menu kuro lori ibo June 12, le ti yi wo, ki awon eni ti mo tako ranse aburu simi loru.
Lesekese ni mo gburo ologbo ni igberi mi nibi ti mo ti dide, o di ologbo dudu, ni o ba bere si ni le mi kiri inu yara, were ni adura bere sii ni bo sile lenu mi.
Laipe ni Tunji, akobi mi ti o sese ti ilu oyinbo de yoju, ti o ri ologbo naa, ni o ba sa pada, omo orogun nnla meji ni ohun ati aburo re yo pada wo ile, la i fa oro gun, won pa ologbo naa.
Bi ile ti mo ni mo ba gbe oku ologbo naa lo si Oyo Igboho, lodo awon agbaagba pe ki won gba mi nnkan ti mo ri re o. won la inu re, won ba owo eyo meta ni inu re ti o fe fi se ose fun mi."
Gomina kan ni aye oloselu keji ni o so gbogbo oro yii, ti ko mo pe ore awon oniroyin timo timo kan wa nibe ti o le tu asiri naa. Ore wa wa bebe pe ohun nikan ni ajeji to wa ni ibi isele naa ti ohun ba da oruko gomina naa, won a mo pe ohun ni oun tu asiri oro yii si gbangba walia.
Eyin eeyan wa, otito gidi ni oro yii, pelu eri aridaju. Gomina oloselu kan ni ile Yooba wa yii naa ni, a da oruko re, a o da gomina Yoruba ni awon aye ran abami ologbo dudu si ni oru.
Gomina naa n so oro yii lekun rere fun awon ebi re ni, ni ojo keji isele naa gan an ni o n so fun awon omo re nnkan ti oju re kan ni aarin oru ki won to gbo igbe ti o fi ta ti awon omo fi sare wole pe ohun o mo awon ti oun se ti won fe ti ibi ologbo dudu mu ohun.

Sunday, June 14, 2009

IDAJO IKU: ADAJO SUN EKUN NI KOOTU.

Awon eeyan miran lero pe bi awon adajo ba ti gbe wiigi won wo, ti won wo aso idajo, o tan ko si oju aanu mo, ti iru awon eeyan bee ba ri Adajo Victor Ovie -Whiskey ti o sun ekun ni kootu ni bi odun meloo kan seyin, won a so wi pe o ba okunrin je, ati wi pe iru nnka yii bu u ku, nitori wi pe gbogbo eeyan ti gba pe akin ni gbogbo adajo.
Nje o se e gbo leti pe iru adajo agba bii ti Ovie-whiskey ti o je eni ti gbogbo eeyan n gboriyin fun nidi ise imo ofin yii, le ma ba odaran ti o jebi iku nigba ti won yiri ejo re wo kinni kinni sun ekun, eleyi yani lenu pupo, sugbon ki a ranti pe Jesu Kiristi naa sun ekun nigba ti Lasaroosi ku.
Adajo Ovie-Whiskey, ti a gbo pe o je olotito eniyan, ti awon ijoba fi se alaga ajo ti o moju to eto idibo idajoba pada f'oloselu eleekeji ti a n pe ni Federal Electoral Commission (FEDECO) ni odun 1983, sun ekun nitori pe ore re ni eni ti o da ejo iku fun.
Lotito okan odaran yii bale nitori wi pe o ri pe ore ohun Ovie-Whiskey ni yoo da ejo fun oun, sugbon adajo Whiskey ni ise re lati se bi o ti to ati bi o ti ye, o yiri ejo naa wo, o si ri pe ko si ona abayo miran ju pe ki ore re ku lo, o sori kodo, o sun ekun kikan kikan, a mo o gbodo mu ofin se, ofin ju gbogbo eeyan lo.
Ninu iforo wani lenu wo lori ero amohun maworan pelu oniroyin kan ni odun 1983, ninu akitiyan re lati mu da awon alaigbagbo loju pe ko si nnkan kan ti o le mu FEDECO lati ma se eto idibo ti o ma waye pelu irowo rose, ibe ni o ti salaye isele ti o sele si enikan ti o mo, ti o ni se pelu ipaniyan.
Ovie-Whiskey mo okunrin naa deledele. Ore timo timo re ni pelu. Ko je tuntun nigba naa, ti odaran naa ba fi okan bale pe ko sewu legberun eko, ore re Ovie-Whiskey ni yoo da ejo naa. Sugbon Whiskey je eniyan olotito inu. O yiri ejo ipaniyan ore re ti won gbe wa si iwaju re wo pelu iberu Oluwa, o si ri daju pe ko si bi ore re yii se le bo lowo idajo iku. Inu adajo naa baje patapata o dori kodo jeje ni aye re, o banu je repete, o sun ekun fun okunrin naa sugbon ofin gbodo se ise re. Ko ti e wo ti aso idajo ati wiigi re nigba ti o fi ki ti eeyan eleran ara bo o, iru ejo ti o bani ninu je be e, se ko o ti i to ki adajo ti o mo to be e ge e ti o fi le sun ekun da iru ejo be e ru ki o je ki o yege?
O rorun lati ri Aare ile Zambia, Kenneth Kaunda ti o sunkun fun ile Adulawo Afirika ni ilu Eko ni odun 1977, ju ki eeyan ri omije loju adajo lo. Ko si bi adajo naa se keere to, koda ki o je omo ile iwe adajo ninu idajo sere sere. A mo sa o, eeyan eleran ara ni awon adajo naa, oun ni adajo Ovie-Whiskey fi han yen.
Adajo Ovie-Whiskey je omo kan soso ni owo iya ati baba re, ko si gbe loju ma a yo sese bi omo kan soso lowo obi, ninu ile ati lenu ise re. O beru Oluwa pupo, eyi ti o si tun gbin si okan iyawo re de bi pe iyawo paapa sun ekun nigba ti o gbo pe won fi oko ohun se alaga ajo FEDECO ni odun 1983, nitori pe ko fe ki won ba oruko rere oko re je.
O so wipe ohun ko nife si bi awon eeyan se pariwo le Ogbeni Ani ti o je eni ti o wa ni ipo naa tele. O ni ise ti o dara ni, amo ko si bi eeyan se ma se ti awon eeyan ko ni fi ibi su ni. Nigba ti o ya, asotele Arabinrin Whiskey bere sii ni se nigba ti awon eeyan bere si ni tako oko re lotun, losi lori bi o se n dari ajo FEDECO nigba naa, awon miran tako o pe ba wo ni o se le pe fun aabo ologun ni akoko idibo.
Awon oloselu fi esun kan wi pe ko te oruko awon oludije jade lasiko, won se eleyii la ti mo bo ya oruko won yoo jade tabi ko ni jade, ki won o le raye fa ijogbon. Won tun so pe ajo FEDECO ko se eto lati ko awon eeyan leko nipa ofin idibo. Won tun pariwo nigba ti o ni ibo Aare ni a o koko di dipo ki a di gbeyin bi ti odun 1979.
Ninu oro re, o ni awon kan so wi pe oun gba opolopo milionu lowo awon eeyan ti oun lo ko pamo si banki loke okun, sugbon, o ni enikeni ninu omo Naijiria ti o ba le jade lati fi idi re mule pe ooto ni oro naa, oun se tan lati jo o ara oun fun ijoba Naijiria lati fi ibon pa oun.
O se alaye wi pe oun ko ni le gbadun ti oun ba ni owo ti o to idaji milionu ni itoju. o ni"eyi le somi di alai ni ifon kan bale mo", gbogbo eyi lo mu ki Adajo Babalakin fi da Adajo Ovie-Whiskey sile wi pe ko wu iwa ibaje kankan nigba ti o je adari FEDECO, nitori pe Babalakin ni o se ayewo si gbogbo ise ti FEDECO se ni odun 1983.
Iwe iroyin Awoko Oga Ede ti gbe iroyin yii jade ri ni odun 2002, osu owara, sugbon inu iwe iroyin Healines ti ile ise Daily Times se ni ati ko jade.

Monday, June 1, 2009

E KA A RO, A O JIIRE BI O.

Iwe Iroyin Awoko yin ti wa tipe, ero ti wa ni lati fun eyin omo iya wa lanfani lati ma ri ede yoruba to yaranti ka lori ero aye lu jara yii.
Aye sa ti di aye ola ju, e je ki awa naa mu asa ti o ba da ninu ibi ti aye ba yi si, ki a ba won se, eyi ni ero wa.
Iwe iroyin AWOKO, yoo ma wa ni ose ose, nnkan ti e o si ma ka nipa re ni awon gbankan gbii iroyin to ti sele koja ti a o ma mu wa fun yin fun iranti awon agbalagba, ati eko fun awon ewe.
A ni yin lokan pupo ni ile ise iwe iroyin okiki, ni a se n sa apa wa lati te yin lorun bo ti le wun ko mo.
Awoko yoo ma mu wa si iranti, awon iroyin isele malegbagbe ni ile wa ati kaakiri agbaye, nigba ti iwe iroyin okiki duro gege bii magasiisni yoruba ti yoo ma tu ikoko awon onise ibi, ti yoo si ma fi ise awon eeyan rere han, ti yoo si ma polongo won fayemo lose ose. Bakan naa ni iwe iroyin wa Iroyin OOjo yoo ma so nnkan ti o ba sele kaakiri agbanla aye lojojumo.
Lede Yoooba nikan ni o, e ku oju lona.